No. 257Mo dupe lowo OluwaLyrics1Mo dupe lowo Oluwa To fi eri ihinrere fun wa To fi edidi otito fun wa Lati soro otito fun aye2Lojo ketadinlogbon Ninu osu November to koja Lowuro kutu loluwa pe mi Pe kin ma lo si ile ilaje3Ni ogbon ojo osu November Mo si dide ona irin ajo mi Mo rekoja ninu ewu motor Mo bo lowo ewu olosa4Gbati mo de Ibajakere Mo soro ihinrere nibe Gbati mo de odun Oyinbo Mo je ise ti Oluwa ran mi5Gbati mo de Ajegunle Nwon si gba oro na tayotayo Gbati mo de ilu Ugbo-Nla Lawrence ni ki omo ogun na mi6Lojo kejo osu December Lawon omo ogun fun mi ni pasan Nwon si tun na awon arakunrin Nwon fi wa se esin eleya7Mo pada sori oke Iwa mimo Lodo awon Aposteli Nwon si tun gba oro ti mo so A se ise emi pupo nibe8Gbati mo de ilu Zion Lodo Aposteli Mafo Mo je ise ti Oluwa ran mi On si soro ijinle fun mi9Mo pada si ilu Ogogoro Mo tun lo si Abe - Alala Mo pada si ilu Maran Mo ri awon to mo otito10Gbati mo de Zion Ipare Gbati mo de ilu Alagbon Ohun ti oju mi ri kose iso Sugbon nwon gba mi t'ayo t'ayo11Mo lo sodo eleri Jehovah Ni ori oke Idi ogba Gbogbo enia to mo mi si ndigbe Wipe otito oro ni mo nso12Oluwa iwo to mu mi lo Je opo iya lodo alaigbagbo Ohun-kohun ti mo ba bere Se fun mi o, Oluwa miAminAbout this hymnWritten byProphet MennaryYear1955TuneO DARA ARA MISimilar hymns1Opo eri te ro - Awon omo Eri nsokun1957 · Orin Iyin ati Ọpẹ4Oba Oloro – foro sakoso lori Ijo Tire1957 · Orin Ijo Zion8Wo pẹtẹlẹ ologo didan1957 · Orin Isipaya9Fi ara re fun Olorun1957 · Orin Isegun Previous256 · Fi ope fun OlorunNext 258 · Di oro Oluwa mu