No. 13 · Orin Ogun Ẹmi ati Igbala · Orin Agbelebu ati IrapadaỌmọ Ọlọrun nlọ s'ogunLyrics1Ọmọ Ọlọrun nlọ s'ogun Lati gbade ọba Ọpagun rẹ si nfẹ lẹlẹ Ta lo nṣọmọgun rẹ.2Ẹni to le mu ago na To le bori irora To le gbe agbelebu rẹ On ni ọmọ ogun rẹ.3Mater ikini to kọ ku Mo ri ọrun si silẹ Tori Oluwa rẹ loke To pe ki o gba on la4Ti on ti idariji lẹnu Ninu irora iku O mbẹbẹ fun awọn to palọ Tani le ṣe bi rẹ.5Ẹgbẹ mimọ awọn wọn ni Ti ẹmi mimọ bale Awọn akọni mejila Ti ko ka iku si.6Nwọn faya ran ida ọta Nwọn ba ẹranko ja Nwọn fọrun wọn lelẹ fun iku Tani le ṣe bi nwọn.7Ẹgbẹ ogun tagba-tewe Tọ'kunrin to'binrin Nwọn yi ile Olugbala ka Nwọn wọ aṣọ funfun.8Nwọn de oke ọrun giga Ninu iṣẹ ati ipọnju Ọlọrun fun wa lagbara Ki a le ṣe bi wọn.About this hymnWritten byProphet MennaryORIN MIMỌ SAINARY ALORESimilar hymns7Ẹmi gbe mi bi edidi si ayeOrin Ogun Ẹmi ati Igbala22Igba ogun ni ki Woli jaOrin Woli, Iran ati Ẹmi Mimọ25Itẹdo ilu daraOrin Sioni ati Ijọ30Awa ọmọ kekekeOrin Agbelebu ati Irapada Previous12 · Oke yi - oke yi - oke yi (2 times)Next 14 · Sọfun mi Olugbala (2 times)