No. 385Igbagbo dara lopolopoLyrics1Igbagbo dara lopolopo Bi enia ba le ni iwa irele Suru dara lopolopo Bi enia ba le fi ara da iya2'Gbati mo siro ojo aiye mi Nipa ife rere ti mo ni Ti omo araiye fin san ibi fun mi O se mi ki nma tun gbagbo mo3Igbagbo ni ikoro pupo Bi enia ba fe ma tele Igbagbo si ni adun pupo Nigbati o ba di ojo idajo4Bi o baje Woli ninu igbagbo Bi o riran rere fun enia Yio ma yin o Nitoripe ori iran rere.5Igbagbo ni iya pupo Ni orile ode aiye Bi aiye te ika bo o lenu Sugbon iwo ko gbodo ja6Bi o ba se rere ninu igbagbo Pupo enia yio ma bu o Bi o se buburu ninu igbagbo Gbogbo enia yio ma bu o7A! Olorun Oba onidajo Kilohun ti emi yio se Tenu aiye yio kuro lara mi Baba Olore lo le segun8Omije si nsan loju mi Tori iya to wa ninu igbagbo Ti emi ko le ko fun Oluwa Tori on ko ko iya fun mi.9Olorun mi - Olorun mi Iwo yio ha koja lodo mi Iwo yio ha mu egan ba mi Ba araiye ti nmu ba mi10Mo siro ife ti mo ti ni Lati kekere di iwoyi Ti omo araiye fin san ibi fun mi Mo mo wipe aiye ko dara.AminAbout this hymnWritten byProphet MennaryOrin Mimo ni Saturday 14/9/57 T.H.S.A Previous384 · 'Gbati Oluwa pa oju re moNext 386 · Kristi OLugbala wo mi