No. 42 · Orin Ẹmi, Iku ati Idajọ · Orin IkilọEnia ti a bi ninu ObinrinLyrics1Enia ti a bi ninu Obinrin Ọlọjọ kukuru nişẹ Nwọn yio dagba nigba owurọ Nwọn yio şubu nigba aşalẹ.2Enia ti a bi ninu Obinrin Gbogbo wa fi iyẹpẹ şe aşọ Igbakan mbọ ti iyẹpẹ yio gbo Ti yio kun ẹmi wa nikan.3Igberaga aşọ wiwọ Ifẹkufẹ bata ti a ndi Gbati iku ba ta ọfa si wa Ao nikan wa ni iboji.4Ọjọ kan mbọ ti iku nwa bọ Erupẹ ti a fi şe aşọ wọ Nigbati oro iku ba mu wa Gbogbo ero wa yio di ofo.5Arakunrin Arabinrin Jẹki a mọ ara wa ni eweko Ọjọ aiye wa nkọja lọ Ori gẹgẹbi ala ti a nrọ.6Anu ṣe mi Ọlọrun mi Omije si nṣan loju mi Bi mo mọ pe ẹda le ku Nko ba wa sori ilẹ aiye.7Ẹnyin ọmọde ati agbagba Ẹjẹ ka pa ofin Baba mọ Bi awa ba ku ninu Adamu Ao jinde ninu Kristi.Amin.About this hymnWritten byProphet MennaryORIN MIMỌ SAINARY ALORESimilar hymns7Ẹmi gbe mi bi edidi si ayeOrin Ogun Ẹmi ati Igbala8A! iwọ igi yi : A! igi yiOrin Ironupiwada12Oke yi - oke yi - oke yi (2 times)Orin Ironupiwada14Sọfun mi Olugbala (2 times)Orin Ọrun ati Iye Ainipẹkun Previous41 · Gbati mo wa ninu ẹmi OluwaNext 43 · Ẹbẹ mo mbẹ Oluwa