No. 485Wo aguntan to joko leti Odo EfrataLyrics1Wo agutan to joko leti Odo Efrata Ti Adaba mimo si nra lori Oke re A! Ayo mi' kun gbati mori adaba na.2Agutan mimo to joko leti Odo Ewure nsumo lati ti sinu Odo Aja si nfo mo adaba na lati mu A! anu ara mi se mi nipa oro iran na.3Wo bi ewure ti nfe ba agutan dogba O nfe fi arekereke wo laso dudu Aja nfe fi etan mu lo je iyagbe A! anu arami se mi nipa oro Iran na,4Bi Olorun ti ngbe awon omo Re saiya Re Be lesu si nfe fi aiye pansaga gbe won O nran ife si won nipa owo Omobinrin aiye A! emi ro ori o nipa oro iran yi.5A! aiye toto aiye alaropin Aiye to nfi iku pa pupo Woli Olorun Won fi etan mu omiran se si Olorun A! Ominu ko mi nipa oro iran yi6Wo bi aiye ti nfe fi etan mu adaba wole Nwon fi Oju re ri ohun ti ki iri Adaba jade kuro larin won A! egbe ni fun aiye nitori ikose.7Wo agutan taiye mu lo fun pipa Nwon di lowo meji ko si yanu Nwon tuto si loju won sin se ni ise A! eru aisedede mi ni Kristi nko lo yi8Bi Kristi ti ko aisedede mi lo to Bi emi ba ndese ti nko sin Kristi Nje emi hale ye lojo idajo A! Moro ori o nitori ojo Oluwa.9Baba wo ate ese, ti esu ngbe ti Mi lojojo Wipe bi nko ba da eyi ki nda omiran Iwo mope alagbara ni esu Jofi emi refo ate esu kuro niwaju mi.10Igi rere hale so eso buburu Iyefu hale wa laiso eso Maje ki Ogo mi yipada di Ogo esu Majeki esu ran mi losi orun apadi.AminAbout this hymnWritten byProphet MennaryOrin Mimo Sainary Alore Previous484 · Bi o se nlo mi lo yi OluwaNext 486 · Enyin ti egbami ihinrere