No. 70 · Orin Adura · Orin Igbagbọ ati ItunuBaba tan imọlẹ Rẹ sọna miLyrics1Baba tan imọlẹ Rẹ sọna mi Ki nle mọna temi o rin si Tete tan mọlẹ Rẹ s'ọna mi Ki nle kuro lokunkun wa yi.2Iwọ to gbọ gbigbin ọmọ Israel Gbati Farao ko wọn lẹru Mo şi ọkan mi paya si Ọ Şe ohun ti mo nfẹ fun mi.3Mo joko sile, ile nnimi Mo joko silu, ilu nlu mi Mo lọ sirin ajo, ajo buru Nibo lemi o rin si o, laiye.4Mo lọ si ila orun kodara Mo lọ si iwọ orun ogun de Mo şe işẹ titi işẹ ko şe Ẹgan aiye şubu lu mi.5Ẹniti o ba ti fi işẹ rẹ ran Ko yẹ ko şagbe ko to jẹ onjẹ Ko yẹ ko faşọ akisa bora Igbese koyẹ ayanfẹ rẹ.6Mo ri kẹkẹ awọn Woli loke Ẹmi gbe mi fo mọ kẹkẹ na Mo fẹ ni iru kẹkẹ na laiye Kẹkẹ ti Jehus fi njagun.7Tilẹkun idanwo aiye fun mi Şilẹkun ibukun rẹ fun mi Iwọ to bukun fun Solomoni Fi ire ti mo nfẹ bukun mi.Amin.About this hymnWritten byProphet MennaryORIN MIMỌSimilar hymns2Bi o se da mi si Oluwa Orin Adura3Iwo oro Olorun - Ogbon ati oke waOrin Ikede Oro Olorun4Oba Oloro – foro sakoso lori Ijo TireOrin Adura10Maṣe ba mi rojọ Oluwa miOrin Ironupiwada Previous69 · Ẹnyin ara oke SioniNext 71 · Oluwa nkigbe tan tan pe