No. 79 · Orin Ekun · Orin Woli, Iran ati Ẹmi MimọAdaba ẹri mi o, nibo lore o ?Lyrics1Adaba ẹri mi o, nibo lore o ? Mennary mi o, nibo lo lọ ? Oju kun mi o, Baba aya pami o Mennary mi pada wa wo mi.2Mo nwo oke ẹri o, Mo nwa Adaba mi o Mo duro ninu ọgba, Nwa Mennary mi Ẹni ri wọn o, ki o pe wọn fun mi o Pe aisan ifẹ nşe mi.3Adaba ẹlẹwa, Alore ologo Ofunfun bi Sno, ati bi ẹgbọn owu Oju nro mi o Baba, tori Menah mi o Ti emi ko ri.4Gbogbo ọmọ Sioni, lọkunrin lobinrin mo bẹyin Bi ẹ ba ri Menah mi o, ki ẹ sọ fun mi o A! oju nro mi.5Adaba Menah, to nkọ mi lorin ọrọ Adaba rere O da iri sori mi, o da ẹwa sara mi A! ogo ọrun6Işẹ nşe mi o, Menah mi o Ẹgan mba mi o, Adaba ẹri rere Ma fi mi silẹ mọ o, fun iya jẹ o A! Adaba rere.7Gbogbo ẹnyin Alore, ati ẹnyin ogun ọrun Mo bẹ yin Bi ẹba ri Adaba mi o, ki ẹ sọ fun mi o Ki ẹpe fun mi.Amin.About this hymnWritten byProphet MennaryORIN MIMỌ SAINARY ALORESimilar hymns9Elo Hermar - Elo HermarOrin Woli, Iran ati Ẹmi Mimọ20Romicinah - Mary Alau-Dauher1956 · Orin Ọrun ati Iye Ainipẹkun21Mo ngbọ ọrọ edidi ọrun 1957 · Orin Woli, Iran ati Ẹmi Mimọ22Igba ogun ni ki Woli jaOrin Woli, Iran ati Ẹmi Mimọ Previous78 · Wo Woli Siloh to ti Judiah sọkalẹNext 80 · Igba aṣalẹ yio ti dun to (2 times)