No. 23 · Orin Woli, Iran ati Ẹmi Mimọ · Orin IkilọIbaṣepe Mose ko wa saiyeLyrics1Ibaṣepe Mose ko wa saiye Ti Ọlọrun ko lo Woli kankan Nibo lawọn Woli iwoyi Yio ti ri iwe ka ?2Nigbati Ọlọrun lo Jọsuah O fun lọrọ ti yio sọ Bi Ọlọrun ba lo Woli kan Yio fun lọrọ sọ.3Tani ninu awọn Woli Ọlọrun ? Ti ngbe iwe fi lọ ma wasu Bikoṣe ki wọn jẹri si Ọrọ iwe mimọ.4Peter jẹri si ọrọ David O tun jẹri sọrọ Joel Ẹmi Kristi lo kọ debẹ Kiṣe iwe lo nka.5Kristi jẹri si ọrọ Isaiah Pe gbogbo wọn yio gbọ ọrọ na Ṣugbọn oye ko ni ye wọn Bẹni Oluwa sọ.6Ẹlẹmi to nsọ ede Ati ariran to nsọtẹlẹ Nibo lasọtẹlẹ yin wa ? Nibo lasọtẹlẹ yin wa ? A! anu ṣe mi.7Gbogbo Woli ti Ọlọrun nlo Nwọn ki ṣe alagbaṣe fun ẹda mọ Awọn Woli aiye iwoyi Jẹ alagbaṣe ẹda.8Ẹbẹ mo mbẹ Ọlọrun mi Ko ba mi tọju ẹbun rẹ to fun mi Baiye tilẹ kọ ẹri rẹ Sa ma lo mi si.Amin.About this hymnWritten byProphet MennaryORIN MIMỌ SAINARY ALORESimilar hymns7Ẹmi gbe mi bi edidi si ayeOrin Ogun Ẹmi ati Igbala9Elo Hermar - Elo HermarOrin Woli, Iran ati Ẹmi Mimọ16Ẹyin ijọ Ugbo-nlaOrin Sioni ati Ijọ20Romicinah - Mary Alau-Dauher1956 · Orin Ọrun ati Iye Ainipẹkun Previous22 · Igba ogun ni ki Woli jaNext 24 · Ajaga Kristi ti mo ru