No. 249Aisan kan wa lara okunrinLyrics1Aisan kan wa lara okunrin Ti eda kan ko le wosan Oruko aisan na lobirin To npa awon akoni A fi akoni ti Olorun nso Lo le bo lowo aisan na Awa lo nfi owo wa fe Ohun ti nmu iku ba wa2Bi o wa lowuro ojo aiye re Ti o fe se ise fun Olorun Gbogbo ebi re yio wipe Wo gbogbo awon elegbe re To lowo, to si ti gbeyawo Gbogbo won si ti bimo Bi o lo se ise, ti o gbe iyawo Aya tun wa ona iku re3Nigbati iwo ba ni obinrin Iwo o layo die 'Gbati o ba mu obinrin de ile Iwo o layo pupo Lojo aipe a iyawo nsokun Wipe otutu npa mi, Obinrin si tun nkigbe pe Oju nko mi inu ndun mi4On yoma kigbe tantan pe Oko mi iku lo de yi Aladura ati awon arıran Ngbadura ko tile gbo On yio digbe si oko re pe Mo fe lo sodo iya mi Elegbogi pupo lo wa To mo aisan to nse mi5Gbogbo enia yio wipe Mu lo sodo baba re 'Gbati nwon de odo baba re Nwon lo sodo alawo Nwon lo sodo elegbogi Nwon teriba fun orisa Onigbagbo da onigbagbe Anu se mi fun akoni6Mo ro igbesi aiye mi Ekun si bo loju mi Obinrin lo pa Adamu Nwon tun pa Samusoni Nwon pa pupo ninu akoni Nwon si tun pa awon ewe Awa la fi owo wa a nra Ohun ti nmu iku ba wa7Awa lofi owo wa fe Idena igbagbo wa Awa lo fi owo wa nra Ohun ti nmu iku pa wa Awa lo fi owo wa fe Ebi orun apadi Ebe ni mo nbe Olorun Ko gbe mi leke aisan yi.AminAbout this hymnWritten byProphet MennaryTuneTori mi ati ihimrereORIN MIMO ISINA ONIGBAGBO Ifihan Ori- 17-Ese 3. Previous248 · Ejeki a fi iyin fun OluwaNext 250 · Ja! Jehovah Baba