No. 67 · Orin Jesu Kristi · Orin Iyin ati ỌpẹOju Kristi ni oju Adaba miLyrics1Oju Kristi ni oju Adaba mi Ti mo nwo loke ẹri to mi Oju ti airẹ ki mu To nfi igba gbogbo ntan imọlẹ.2Bi gbogbo aiye ko yin Ọ Baba Emi ti şe ileri igbagbọ rẹ Nipa oju mimọ rẹ ti mo ri Mo mọ pe oju ifẹ ni.3Ẹ ji dide ẹnyin koriko Ẹ fi imọlẹ han ẹnyin itanna Gbogbo ikukun ẹda kuro Ki Orun ati Oşupa tan mọlẹ.4Imọlẹ Kristi nran si mi Fi iran rẹ kun inu ati ọkan mi Ki nle foju Ọlọrun han Fun gbogbo awọn ti ko ri.5Iwọ itanşan ẹlẹwa Iwọ oju adaba ẹri Irisi rẹ wu mi pupọ Ọlọrun mi Ọlufẹ mi.6Gbogbo ẹwa aiye yio baje Şugbọn ẹwa rẹ ki baje Pin fun mi ninu ẹwa rẹ Ki nle wa ninu ẹwa rẹ.7Iwọ imọlẹ iyebiye To nşe amọna ara igbani Jọ tan imọlẹ rẹ si mi Şe mi pe ninu ẹwa rẹ.Amin.About this hymnWritten byProphet MennaryORIN MIMỌSimilar hymns1Opo eri te ro - Awon omo Eri nsokun1957 · Orin Iyin ati Ọpẹ4Oba Oloro – foro sakoso lori Ijo TireOrin Adura5Gborin didun kan ti mo gboOrin Jesu Kristi6Geography ọrun ti Ọlọrun fi fun wa1959 · Orin Iwa Mimọ Previous66 · Bi mo ti nnaga nwa ogo ọrunNext 68 · Funfun gbo, lọrọ Ọlọrun